MÁKINDÉ Ń S’Ọ̀YỌ́ DỌ̀TUN, ILÉ IṢẸ́ ỌKỌ̀ ÒFURUFÚ GREEN AFRICA BALẸ̀ GÌJÀ S’ÍBÀDÀN

0 177

Ìmọ́tótó borí àrùn mọ́lẹ̀, bí ọyẹ́ ṣe é borí ooru, àyíká tó mọ́ tóní latọ́kùn ìlera tó péye, ilẹ̀ Àkùọ̀ ní í ṣe atọ́kùn fún ewébẹ̀ tútù, ilẹ̀ tó lẹ́tù lójú ní í sèèso, múrúgbìn rere.

Bí ọ̀ọ̀dẹ̀ ò dùn, ṣebí bí ìgbẹ́ ni ìlú ń rí ? Bí ìlú bá ṣì kan bóbó ńkọ́? Ọmọ t’álákà(àti olówó) wo ni yó ròde ẹmu? Ìfọ̀kànbalẹ̀ ní í muni dárà ìrọ̀rùn.

Sarumi

Ní òpin ọ̀ṣẹ̀ tó kọjá yìí ni ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú Green Africa ṣé ayẹyẹ ìgbérasọ ní pápá ọkọ̀ òfurufú Alákíá Ìbàdàn tí í ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, níbi tí Igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ Amòfin. Báyọ̀ Lawal ti lọ sojú Gómìnà Ṣèyí Mákindé níbi ayẹyẹ ọ̀hún.
Ní kété tí ilé -iṣẹ́ ọ̀hún sí kéde iye owó tí àwọn oníbàárà wọn yó máa san láti ìbàdàn sí èyíkéyìí ìlú ni àwọn mẹ̀kúnnù ti ń yọ ṣẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n ti ń kan sáárá tó ga sí Gómìnà Mákindé nítorí iṣẹ́ àgbéga/ìgbésókè tó ṣe fún pápá ọkọ̀ òfurufú ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìbàdàn yìí, àti àtúnṣe òpópónà tó wọ pápákọ̀ náà ló fá sábàbí èyí, èyí ló wú àwọn Green Africa lórí láti ṣe òkòwò pẹ̀lú pápákọ̀ náà.

Yàtọ̀ sí tí owó tí kò fa àpò ya(₦6,500) tí àwọn ilé iṣẹ́ yìí ṣe àgbékalẹ̀ ọkọ̀ wọn, yó mú àdínkù bá ìrora ojú pópó tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ arìnrìnàjò máa ń dojú kọ lójú ọ̀nà Èkó sí Ìbàdàn, àbí kín ló kan bàlúù pẹ̀lú títì ò dáa? Bákan náà ni yó mú ìrìnàjò yá kánkán.

Monumental Legacy

A dúpẹ́ pé a ò bẹ onígbàjámọ̀ ní asọ rírán ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, a dúpẹ́ pé a ò gbé ìlẹ̀kùn wa fún mọlémọlé pé kó báwa tún un ṣe, ìka tó tọ́ símú la fi re imú, ẹni tó tọ́ l’Adániwáyé fi ṣe Olórí wa, ká fi àdúrà tìí lẹ́yìn kò lè tukọ̀ ìpínlẹ̀ yìí gòkè àgbà.

Láti Ọwọ́:

Ayélabẹ́gàn Akínkúnmi Abbas
Ọmọ Ẹgbẹ́ GSM ADVOCATES
Ìjọba Ìbílẹ̀ Ìwọ̀-Oòrùn Ọ̀yọ́
08134856062